Download Adeyinka Alaseyori – Ire Iran (Mp3, lyrics, Video)

0


Adeyinka Alaseyori – Ire Iran (Generational Blessings)
Adeyinka Alaseyori – Ire Iran (Generational Blessings)

Super Star Minister And Nigerian Christian Gospel Song Musician Adeyinka Alaseyori Releases A Spirit-filled Song Titled “ Ire Iran (Generational Blessings) ” Mp3 Download, “ Ire Iran (Generational Blessings) ” Song Also comes with the Mp3 Audio With A unique Lyrics And The official Video.

This Song “ Ire Iran (Generational Blessings) ” is an interesting Project that will surely worth a place in your heart if you are a lover of nice Gospel music.

Download Ire Iran Mp3 By Adeyinka Alaseyori

DOWNLOAD MP3

Ire Iran video By Adeyinka Alaseyori

Ire Iran lyrics By Adeyinka Alaseyori

Awọn kan kuuu, lai si imuṣẹ ileri
Ọlọrun mi o fẹ
Awọn kan feti gbọ ileri titi titi
Ṣugbọn ko pada ṣẹ Ọlọhun
Ileri ti mo gbọ ninu Bibeli
At’eyi ti mo la loju alaa
Eyi ti mo ri ninu iran
Ati isotẹlẹ

Ire ire, ire iran mi oo
Tete ṣẹ lori mi, tete ṣẹ
Ma jẹ nku k’ogo to de oo
Ire iran ṣẹ mọ mi lara
Iran ire jọ ṣẹ mọ mi lara oo
Ire iran, iran ire, tete ṣẹ

Pataki pataki ni wipe, imuṣẹ ileri
Aka imọye ileri t’ati feti gbọ
Ti o ba imuṣẹ pade oo
Idaduro ileri, Idaduro ala tabi iran
O le mu k’ọmọ ologo maa rare o
Akoko imuṣẹ ileri o to, ire iran ṣẹ mọ mi l’aara
Gbogbo idile lo ni ire iran ati ibi iran
Ehh atiṣe
To je wipe egun iran lo n tẹle ọpọlọpọ kiri
Ire iran mi da oo, akoko imuṣẹ to oo
Ọlọrun
Awọn ti mo f’ọrọ lọ t’wọn ṣa ogo mi lọgbẹ
Awọn ti mo gbara le
To jẹ pe ẹgun l’ọn fi s’ara
Awọn ti mo sọ iran fun
Ti wọn ri iran ki n to ri
Ti wọn transform ẹ
Ti wọn exchange ẹ f’ọmọ wọn
Tabi ẹṣẹ mi, aṣiṣe mi
Ẹṣẹ iran mi, ẹṣẹ awọn obi mi
Ẹṣẹ ibi ti mo gbe, ile ti mo kọ, ibi ti mo ti n ta’ja
Gbogbo ẹṣẹ to le ma da imuṣẹ iran duro
Ọlọrun, dari ji mi oo
Ọlọrun, wọn lo ma n dahun adua oo
Ọlọrun, o ma n dahun adua oo
Imuṣẹ ileri mi da oo
Imuṣẹ ileri mi da oo

Melo nigba to ti gbọ pe o ma travel
O wọ local flight ri
Ọpọlọpọ gan-an dẹ ti rin irin ajo gan-an lọ ilu ọba
Ṣugbọn sibe sibe, imuṣẹ ileri o tii ṣẹẹ
Melo nigba to ti gbọ pe o ma loyun
Oyun kan o duro ri, imuṣẹ ileri lo nilo oo
Melo melo ni awọn ọdọ
Tọn l’awọn logo to ma gbe ile ga at’orilẹ ede
Awọn nọn rare kiri
Imuṣẹ, imuṣẹ ire iran da oo

Aimọye ẹṣẹ ikọkọ to o ni
T’iwọ funra ara rẹ damọ
To onilo imuṣẹ le lori
Mu ti ẹ, ko bẹrẹ si ni bere imuṣẹ
Bere imuṣẹ ileri ogo
Aimọye awọn ọmọ to mọwe tẹlẹ tẹlẹ
Ṣugbọn t’aye pa kadara wọn da lojiji
Ọmọ to jẹ akinkanju, to mọwe gidi
O wa dẹni to n ṣẹru labẹ ero
Iwọ naa bere fun imuṣẹ ileri
Bere fun imuṣẹ ileri
Iṣẹ to n ṣe yẹn lọpọlọpọ la
Ti wọn fi yan ti wọn fi yanju
Lọgan to dawọ le, gbogbo rẹ doju de
Kilode, imuṣẹ ileri lo nilo oo
O ti n ṣe fun ọdun mọdun, oṣu moṣu
Tọ Ọlọrun lọ fun imuṣẹ ileri
Ani agbẹjọro nla, Jeeesu lorukọ rẹ oo

Ogo o gbudọ ba mi niboji
Eewọ mi ni
Imuṣẹ ire iran
Ko gbudọ ba mi lọgba were
Eewọ mi ni
Akoko too lati dide lori ọrọ mi
Oluwa dide

Ire ire, ire iran mi oo
Tete ṣẹ lori mi, tete ṣẹ
Ma jẹ nku k’ogo to de oo
Ire iran ṣẹ mọ mi lara
Iran ire jọ ṣẹ mọ mi lara oo
Ire iran, iran ire, tete ṣẹ

Ẹrin mi o gbudọ ba mi ni iboji oo
Ẹrin mi o gbudọ ba mi ni iboji oo
Igba t’ogo ba deee
Ẹmi mi o gbọdọ pin lojiji
Ẹrin o gbudọ ba mi ni iboji oo
O ti lọla ri ko lọla mọ
Ko ki ṣe ipin mi oo
Ẹyin tẹ n duro lati ja mi bọ lojiji
Ẹ maa duro lasan
Ẹyin tẹ n reti ọjọ tẹ ma gbọ iku mi
Iku ọmọ, iku ọkọ
Emi ni n maa f’eeru f’eru yin
Ati iyẹpẹ fun iyẹpẹ yin
Ẹ o ni rẹ rin kẹyin lori ọrọ mi
Ẹrin o ni ba mi ni iboji oo
Awọn ton wo mi l’oke tọn fẹ kin jabọ
Awọn ton reti ipadabọ olowo
Si talaka lori mi, eewọ ni
Ẹrin, gbọ, nigba ti imuṣẹ ba de
O gbudọ ba mi ni iboji oo
Ti ẹrin ba de tan
Ti iranlọwọ ba de
Ti igbedide ba de, ati idahun adua
Wọn o ni fimi pitan ogo
Wọn o ni fimi pitan buburu ninu ogo
Ẹrin, ẹrin, o gbudọ ba mi ni iboji oo
O n logo lọwọ n’iku ba de, ki n ṣe ipin rẹ
Awọn ọmọ to ma n ṣe fun ẹ jẹ
Wọn o ni da ẹmi wọn le gbodo lojiji lori ọrọ rẹ
Ogo, t’Ọlọrun fi ta ọ lọrẹ
O ni f’ọwọ rẹ gb’ọmọ sin oo
Ẹrin, oo gbudọ ba mi ni iboji oo

Nigba t’ẹrin ba de tan
Ti ogo ba de tan
Aleluya lorin mi
Aleluya lorin mi
Aleluya, ko ni tan
Lẹnu mi si ọọ oo
Iwọ to gba kile mi o dahoro titi laye laye
Aleluya lorin mi si ọ

N o ma kọrin wipe
Igba kan riii, mo n tọrọ jẹ
Igba kan riii, mo n f’ogo rare
Lọjọ ti mo ti mọ, Olodumare
Laye mi yi pada
Igba mi dọtun ninu rẹ
Lọjọ ti mo ti mọ, Olodumare
Laye mi yi pada
O yi pada si ire

SHARE

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here